OLORI ijo t’ orun

by YBH 564

1. OLORI ijo t’ orun, L’ ayo l’ a wole fun O; K’ o to de, ijo t’ aiye, Y’o ma korin bi t’ orun, A gbe okan wa s’ oke, N’ ireti t’ o n’ ibukun; Awa kigbe, awa f’ iyin F’ Olorun igbala wa. 2. Bi a wa ninu ‘ponju, T’ a nkoja ninu ina, Orin ife l’ awa o ko. Ti o mu wa sunmo O; Awa sape, a si yo, Ninu ojurere Re Ile t’ o so wa di Tire, Y’o pa wa mo titi lai. 3. Iwo mu awon enia Re Koja isan idanwo; A ki o beru wahala, ‘Tori O wa nitosi, Aiye, ese at’ Esu, Kojuja si wa lasan, L’ agbara Re, a o segun, A o si ko ‘rin Mose. 4. Awa f’ igbagbo r’ ogo, T’ O nfe lati fi wa si, A kegan ere aiye, Ti a fi siwaju wa, Bi O ba si ka wa ye, Awa pelu Stefen t’o ku Y’o ri O bi o ti duro Lati pe wa lo s’ orun.