NIPA ife Olugbala

by YBH 253

1. NIPA ife Olugbala, Ki y’o si nkan; Oju rere Re ki pada. Ki y’o si nkan. Owon l’eje t’o wo wa san, Pipe l’edidi or’-ofe, Agbara l’owo t’o gba ni, Ko le si nkan. 2. Bi a wa ninu iponju, Ki y’o si nkan: Igbala kikun ni ti wa. Ki y’o si nkan. Igbekele Olorun dun, Gbigbe inu Kristi l’ere, Emi si nso wa di mimo Ko le si nkan. 3. Ojo ola yio dara, Ki y’o si nkan. ‘Gbagbo le korin n’iponju Ki y’o si nkan A gbekele ‘fe Baba wa, Jesu fun wa l’ohun gbogbo. Ni yiye tabi ni kiku Ko le si nkan.