"KI LO WE ESE MI NU

by YBH 403"

1. KIL’ o le w’ ese mi nu? Ko si, lehin eje Jesu; Kil’ o tun le wo mi san? Ko si, lehin eje Jesu. A! eje ‘yebiye, T’ o mu mi fun bi sno, Ko s’ isun miran mo, Ko si lehin eje Jesu. 2. Fun ‘wenumo mi, nko ri, Nkan mi, lehin eje Jesu; Ohun ti mo gbekele Fun ‘dariji, l’ eje Jesu. A! eje ‘yebiye, T’ o mu mi fun bi sno, Ko s’ isun miran mo, Ko si lehin eje Jesu. 3. Etutu f’ ese ko si, Ko si lehin eje Jesu; Ise rere kan ko si, Ko si, lehin eje Jesu. A! eje ‘yebiye, T’ o mu mi fun bi sno, Ko s’ isun miran mo, Ko si lehin eje Jesu. 4. Gbogbo igbekele mi, Ireti mi l’ eje Jesu; Gbogbo ododo mi ni. Eje, kiki eje Jesu. A! eje ‘yebiye, T’ o mu mi fun bi sno, Ko s’ isun miran mo, Ko si lehin eje Jesu.