JESU y’o joba ni gbogbo

by YBH 453

1. JESU y’o joba ni gbogbo Ibit’ a ba le ri orun; ‘Joba Re y’o tan kakiri, ‘Joba Re ki o n’ ipekun. 2. On l’ ao ma gb’adura si, Awon oba y’o pe l’ Oba; Oruko Re b’orun didun, Y’o ba ebo oro goke. 3. Gbogbo oniruru ede, Y’o f’ ile Re ko ‘rin didun; Awon omode y’o jewo Pe, ‘bukun won t’ odo Re wa. 4. ‘Bukun po nibit’ On joba; A tu awon onde sile; Awon alare si simi; Alaini si ri ‘bukun gba. 5. Ki gbogbo eda k’ o dide, Ki nwon f’ ola fun Oba won; K’ Angel’ tun wa t’ awon t’ orin Ki gbogb’ aiye jumo gbe ‘rin.