GBAT, a b’Oluwa rin

by YBH 277

1. GBAT, a b’Oluwa rin N’nu ‘mole oro Re Ona wa yi o ti l’ogo to! ‘Gbat’ a ba nse f’e Re On y’o ma ba wa-gbe Ati awon t’o gbeke won le. Sa gbekele Ona miran ko si Lati l’ayo n’nu Jesu, Afi k’a gbekele. 2. Ko si ajaga mo Ko si ‘banuje mo Gbogbo wahala wa ti pari Ko si arokan mo, Tabi ifajuro, Afi ‘bukun, t’a ba gbekele 3. Awamaridi ni Ayo ife nla Re Titi ao fi f’ara wa rubo, Anu ti O nfi han, At’ ayo t’O nfun ni Je ti awon ti o gbekele 4. Ni idapo didun L’ao joko l’ese Re Tabi ki a ma rin pelu Re, Awa y’o gbo ti Re, Ao jise to ran wa, Mase beru sa gbeke re le