EWOLE f’ Oba, ologo julo

by YBH 8

1. EWOLE f’ Oba, ologo julo, E korin ipa ati ife Re; Alabo wa ni, at’ Eni Igbani, O ngbe ‘nu ogo, eleru ni iyin. 2. E so t’ ipa Re, e so t’ ore Re: ‘Mole l’ aso Re gobi Re orun, B’ ara ti nsan ni ‘keke, ibinu Re; Ipa ona Re ni a ko si le mo. 3. Aiye yi pelu ekun re gbogbo, Olorun, agbara Re l’ o da won: O fi idi re mu ‘le, ko si le yi, O si f’ okun se oja igbaiya re. 4. Itoju Re wa lara gbogbo won, Ninu afefe, ninu imole; Itoju Re wa nin ‘ odo ti o nsan, O si wa ninu iri ati ojo. 5. Awa erupe, aw’ alailera, ‘Wo l’ a gbekele, O ki o da ni; Anu Re ronu, o si le de opin Eleda, Alabo, Olugbala wa. 6. ‘Wo alagbara, onife julo, B’ awon angeli ti yin O loke, Be l’ awa eda Re niwon t’ a le se A o ma juba Re, a o ma yin O.