CCC Hymn 621
by Celestial Hymn
1: Maleka Mimo t’Orun,
Nwon ti t’Orun sokale,
Lati wa sure fun wa,
Ninu Ijo Mimo.
2: Enyin omo Ijo Mimo,
Mura lati se ife Re,
Nitori o mbo kankan,
Lati be wa wo.
3: Gbogbo ‘enyin oluponju,
E korin ke ho f’ayo,
Nitori Oluwa mbo,
Yio da yin nide.
4: Ayo wa yio ti po to,
Nikehin ni Ijoba Orun,
Bi awa ba le mura,
S’ise Oluwa.
5: Enyin O sise Oluwa,
Mura lati sise na,
Nitori ere nyin po,
Li oke Orun
Amin