CCC Hymn 539
by Celestial Hymn
1: Aiye yi ti wo segbe kan,
Satani nkiri fun itiju,
Elese yara wo ‘ko ikehin,
Ko ma ba je eni ta o feku.
2: Anu Baba ti nfe dopin,
Ki o tun gbohun adura mo,
Rukerudo ajakale arun,
Ati ‘ponju ti sunmo aiye.
3: Baba ko fe egbe elese,
Beni ko si fe iku won,
Wa sodo Mi l’Olugbala nwi,
Emi yio si gba gbogbo yin la.
4: Gbogbo yin, e po ninu ife,
Pelu isesi tododo,
E ma gbadura nigbagbogbo,
Emi O si wa pelu yin dopin. Amin