CCC Hymn 377
by Celestial Hymn
1: E je k’a fope fun Baba,
Jehovah Olodumare,
Eleda Orun aiye,
2: On lo da Orun meje,
Ati ile meje pelu,
Orun ati Osupa,
Ti ntanmole yi wa ka.
3: O fi onje fun gbogbo eda,
Eiye iwo to nfo koja,
Ti k’ogbin, ti ko kore,
Ati eranko igbe.
4: E ba wa, yin Oluwa,
Ologo ti ko nipekun,
Ona okiki Imole,
Oba Olusegun wa,
5: Jehovah, Mimo, Mimo, Mimo,
F’oju rere Re wo wa,
Ko si ma samona wa,
Ninu Ijo Mimo yi.
6: Jesu Kristi, Olugbala,
F’ igbala Re kari wa,
Ka be ninu ese,
Nitori isun eje Re.
7: Michael Mimo. Balogun wa,
Olugbeja ‘won eni Mimo,
Gbe ida re soke fun wa,
Lati segun emi esu.
8: Ogo ni fun Baba l’Orun,
Ogo ni fun Omo Re,
Ogo ni fun Emi Mimo,
Meta lokan aiyeraiye.
Amin