CCC Hymn 291
by Celestial Hymn
1: Oro Oluwa ko si yin,
Latoke Orun wa,
E mura, ke gbo ipe na,
Ke si ri ogo na.
2: Aiye yi yio lo si opin,
Ohun gbogbo yio tan,
Enikeni to gbo oro na,
Yio si ri ogo na.
3: Ijo Mimo e tun ra di,
Ke le kun aye yin,
Aye ti Jesu wa sile,
Ti yin ni yio je.
4: Ife Oluwa ti po to,
S’enyin Ijo Mimo.
E mura ke gb’Oluwa gbo,
Ke le ri ogo Re.
5: Eyin, aiye ke mo daju,
P’asan laiye yi je,
Oro Oluwa ododo,
Ni yio je nikehin.
6: A de Mimo t’Emi ti pese,
F’awon to gba Mi gbo,
Awon to gbagbo yio dade na,
Lati sogo kehin.
Amin