CCC hymn 276
by Celestial Hymn
1: E ba wa yo, ara ninu Kristi,
Fun o ri rere ta ni,
Wakati buburu na de,
Ti o mu aiye yi gbona,
Elese ronupiwada,
Ni ‘jo Mimo yi.
2: Ogbun nla si sile nisisiyi,
Lati t’eruku jade,
Bo ko ba fe jeni egbe,
Si odo Olugbala Re,
Romo Kristi ‘nu Ijo Mimo yi,
Yio ran o lowo.
3: Laipe, baba ki yio mo omo,
Tab’ omo mo baba mo baba re,
K’aiye sile sa to Kristi,
O duro loke Mimo Re,
Rukerudo ‘parun nla mbo,
Ya ronupiwada.
4: Mo si tun nduro ninu anu mi,
Npe awon elese,
Wakati yi e pawada,
Laipe anu yio dopin,
Fi ‘ka, aje, orisa sile,
Kristi yio, gba wa la.
5: Gbogbo ekun aiye ti se simi,
Sibe nko bikita,
Nko ro ewa ti Orun,
Kika ni irun yin,
Lomu Emi Kristi jiya na,
Emi ni, wa, ki o ye.
6: Niti iparun ti aiye yi,
Mo fi anu fa sehin,
Sibe aigbagbo nposi,
Nwon nsin orisa, aje,
Nwon lo arakan ati ika,
Fi won le wa ‘do Mi.
7: Mo ti pese ohun rere fun o,
Ade didan iye na,
Bugbe re nduro de o,
Lori ile didara na,
F’aiye sile, wa sodo Mi,
Emi o tewo gba o.
Amin